Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ohun t...
O ni alaafia
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe gbogbo iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ìdájọ́ yii kárí gbogbo iṣẹ́ bii ìjọsìn ati ibalopọ. Ẹni ti o ba gbèr...
Lati ọdọ 'Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu alamọri wa...
O ni alaafia
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu ẹsin tabi ti o ba ṣe iṣẹ kan ti ẹri kankan ko da le e...
Láti ọ̀dọ̀ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Láàrin ìgbà tí a wa ni ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan,...
O ni alaafia
Muslim gba a wa

Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe Jibril wa ba àwọn saabe ni àwòrán arákùnrin kan ti wọn kò mọ̀. Lára àwọn ìròyìn rẹ ni pe àwọn aṣọ r...
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Wọn mọ Isilaamu pa lori...
O ni alaafia
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi Isilaamu jọ ile kan ti wọn mọ daadaa pẹlu origun maarun ti o gbe ile naa duro, ti awọn iwa Isilaamu ti o s...
Lati ọdọ Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori kẹtẹkẹtẹ kan ti wọn n pe ni ‘Ufair, o sọ p...
O ni alaafia
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin, ati iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun, ati pe iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni...

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe gbogbo iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ìdájọ́ yii kárí gbogbo iṣẹ́ bii ìjọsìn ati ibalopọ. Ẹni ti o ba gbèrò anfaani kan pẹlu iṣẹ rẹ, anfaani yẹn naa ni o maa tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́, ko si si ẹsan kankan fun un, ẹni tí ó bá wa gbèrò isunmọ Ọlọhun pẹlu iṣẹ rẹ, o maa gba ẹsan kódà ki o jẹ iṣẹ lásán bii jijẹ ati mimu. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa fi àkàwé lélẹ̀ láti ṣàlàyé ilapa àníyàn nibi awọn iṣẹ pẹ̀lú didọgba wọn nibi àwòrán ti o hàn, o wa ṣàlàyé pe ẹni ti o ba gbèrò wíwá ìyọ́nú Ọlọhun pẹ̀lú hijra rẹ ati fifi ìlú rẹ sílẹ̀, hijra rẹ nǹkan ti o ba òfin mu ni ti a si maa tẹ́wọ́ gbà ti wọn si maa san an ni ẹsan lórí ẹ fun àníyàn òdodo rẹ, ẹni tí ó bá gbèrò anfaani ayé pẹ̀lú hijra rẹ, bii owó, tabi ipò, tabi òwò, tabi ìyàwó, anfaani yẹn ti o gbèrò naa ni o maa ri nibi hijra rẹ, ko si nii gba ẹsan.
Hadeeth details

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu ẹsin tabi ti o ba ṣe iṣẹ kan ti ẹri kankan ko da le e lori ninu Kuraani ati sunnah, wọn maa da a pada fun ẹni ti o ba ṣe e, ko nii jẹ ìtẹ́wọ́gbà lọdọ Ọlọhun.
Hadeeth details

Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe Jibril wa ba àwọn saabe ni àwòrán arákùnrin kan ti wọn kò mọ̀. Lára àwọn ìròyìn rẹ ni pe àwọn aṣọ rẹ funfun gan, ti irun rẹ naa si dudu gan, wọn ko ri oripa ìrìn-àjò lára rẹ bii híhàn wàhálà, ati eruku, ati ki irun ri wúruwùru, ati ki aṣọ dọ̀tí, ẹni kankan ko si mọ ọn ninu awọn ti wọn wa ni ìkàlẹ̀, ti wọn si jókòó ni ọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a), ni o wa jókòó ni iwájú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ìjókòó akẹ́kọ̀ọ́, o wa bi i leere nipa Isilaamu, o wa da a lóhùn pẹ̀lú àwọn origun ti o ko fifi ijẹrii mejeeji rinlẹ sínú, ati mimojuto irun wákàtí márùn-ún, ati yíyọ sàká fun awọn ti wọn ni ẹtọ si i, ati gbigba aawẹ oṣù Ramadan, ati pípé ọranyan hajj fun ẹni tí ó bá ni ikapa. Onibeere wa sọ pé: Òdodo ni o sọ, àwọn saabe wa ṣe eemọ latara ìbéèrè rẹ ti n tọka si àìní imọ rẹ ti o hàn si wọn, lẹ́yìn náà ni o tun wa n sọ pe òdodo ni o sọ. Lẹ́yìn naa ni o bi i leere nipa igbagbọ, o wa da a lóhùn pẹ̀lú àwọn origun mẹ́fà yii ti o ko igbagbọ ninu bibẹ Ọlọhun ati awọn ìròyìn Rẹ sinu, ati ṣíṣe E ni Ọ̀kan pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ Rẹ bii dídá ẹ̀dá, ati ṣíṣe E ni Ọkan pẹlu ìjọsìn, ati pe àwọn malaika ti Ọlọhun da latara imọlẹ ẹrú alapọn-ọnle ni wọn, wọn kii yapa àṣẹ Ọlọhun, ati ìgbàgbọ́ nínú àwọn tira ti a sọ̀kalẹ̀ fun awọn ojiṣẹ lati ọdọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, gẹgẹ bii Kuraani, ati Taoreeta, ati Injiila, ati eyi ti o yatọ si wọn, ati ìgbàgbọ́ nínú àwọn ojiṣẹ ti wọn n ba Ọlọhun mu ẹsin Rẹ de ọdọ àwọn èèyàn, ninu wọn ni Nuuh, ati Ibrahim, ati Musa, ati Isa, ìgbẹ̀yìn wọn ni Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a), ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn Anọbi ati awọn Ojiṣẹ, ati ìgbàgbọ́ ninu ọjọ́ ìkẹyìn, ohun ti n bẹ lẹyin ikú ti ko sínú rẹ̀ bii sàréè ati iṣẹmi lẹ́yìn ikú, ati pe wọn maa gbe ọmọniyan dìde lẹ́yìn iku, o si tun maa ṣe ìṣirò, nínú ki ìkángun rẹ jẹ alujanna tabi iná, ati ìgbàgbọ́ pe Ọlọhun ti kádàrá gbogbo nǹkan ni ibamu si ohun ti O ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, ti o si ba ọgbọ́n Rẹ̀ mu ati àkọsílẹ̀ Rẹ, ati fifẹ Rẹ fun un, ati ṣiṣẹlẹ rẹ ni ibamu si ohun ti O kádàrá, ti O si dá a fun un. Lẹyin naa ni o bi i leere nipa ṣíṣe dáadáa, o wa sọ fún un pé ṣíṣe dáadáa naa ni ki o maa jọ́sìn fun Ọlọhun bii pe o n ri I, ti ko ba wa le de ipò yii, Ki o yaa maa jọ́sìn fun Ọlọhun bii pe Ọlọhun n ri i, akọkọ ni ipò rírí, oun ni o si ga jù, ìkejì ni ipò ìpayà Lẹ́yìn naa o bi i leere pe igba wo ni ayé maa parẹ? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé pe Ọlọhun nikan ni O mọ ìgbà tí ayé maa parẹ, ẹda kankan ko mọ̀ ọ́n, ati ẹni ti wọn n beere nipa rẹ lọ́wọ́ rẹ ni ati ẹni tí n beere. Lẹyin naa ni o bi i leere nipa awọn àmì ti ayé ba fẹ parẹ? O wa ṣàlàyé pe nínú àwọn àmì rẹ ni ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ẹrú lóbìnrin ati awọn ọmọ wọn, tabi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣiṣẹ ìyá lati ọwọ àwọn ọmọ wọn ti wọn maa ba wọn lo bii ẹrú, wọn maa tẹ́ ayé silẹ fun àwọn adaranjẹ ati awọn tálákà ni ìgbà ìkẹyìn, wọn maa ba ara wọn ṣe iyanran nibi ṣíṣe ilé ni ọ̀ṣọ́ ati kíkọ́ ọ. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé onibeere naa ni Jibril, o wa lati wa kọ́ àwọn saabe ni ẹsin ti o dúró tọ́ yii.
Hadeeth details

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi Isilaamu jọ ile kan ti wọn mọ daadaa pẹlu origun maarun ti o gbe ile naa duro, ti awọn iwa Isilaamu ti o sẹku jẹ pipari ile naa. Akọkọ awọn origun yii ni: Ijẹrii mejeeji; ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Rẹ ni, ati pe origun kan ni mejeeji; ti ọkan o lee ja kuro lara ìkejì, ẹru o sọ mejeeji ni ẹni ti n fi ijẹ ọkan ṣoṣo Ọlọhun ati lilẹtọọ Rẹ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo laisi ẹlòmíràn yatọ si i rinlẹ, ti yio si maa ṣiṣẹ tọ awọn nkan ti o n tọka si, ki o si tun gba iransẹ Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - gbọ ni ẹni ti yio maa tẹle e. Origun keji ni: Gbigbe irun duro, oun naa ni awọn irun ọranyan marun-un ni ojumọ kan ati oru kan: Alufajari, ati Àílà, ati Alaasari, ati Magribi, ati Ishai, pẹlu awọn majẹmu wọn ati awọn origun wọn ati awọn ọranyan wọn. Origun kẹta ni: Yiyọ zakah ọranyan, oun naa ni ijọsin owo ti o jẹ dandan nibi gbogbo dukia ti o ba ti to odiwọn ti wọn fi aala si ninu shariah, ti wọn o fun awọn ti wọn ni ẹtọ si i. Origun kẹrin ni: Hajji, oun naa ni gbigbero Makkah lati gbe awọn iṣẹ ìjọsìn duro, ni ti jijọsin fun Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn. Origun karun-un ni: Aawẹ Ramadan, oun naa ni kikoraro nibi jijẹ ati mimu ati nkan ti o yatọ si mejeeji ninu awọn nkan ti o le ba aawẹ jẹ pẹlu aniyan jijọsin fun Ọlọhun, lati igba ti alufajari ba ti yọ titi ti oorun yio fi wọ.
Hadeeth details

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin, ati iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun, ati pe iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ni Oun nikan ṣoṣo ki wọn si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, Ati pe iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ awọn ti wọn mu U ni Ọkan ti wọn ko da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ. Lẹyin naa Mu’aadh sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, njẹ mi ko nii fun awọn eniyan ni iro ki wọn le dunnu pẹlu ọla yìí? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ fun un ni ti ipaya ki wọn maa gbe ara le e.
Hadeeth details

Mu’aadh ọmọ Jabal- ki Ọlọhun yọnu si i- wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori nǹkan ọ̀gùn rẹ, o wa pe e: Irẹ Mu’aadh? O paara pipe e rẹ lẹẹmẹta; lati fi pataki nnkan ti o fẹ sọ rinlẹ. Ati pe gbogbo ìyẹn ni Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i- n da a lohun pẹlu ọrọ rẹ pé: “LABBAEKA YAA ROSUULALLOOHI WA SAHDAEK”, o n túmọ̀ sí pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun ni idahun kan lẹyin idahun, mo si n tọrọ oriire fun jijẹ ìpè rẹ. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pe ko si ẹnikẹni ti o n jẹrii pe LAA ILAAHA ILLALLOOH, itumọ rẹ ni pe: Ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ afi Ọlọhun, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, lododo lati inu ọkan rẹ lai parọ, ti o ba ku lori iṣesi yii, Ọlọhun maa ṣe ina leewọ fun un. Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i- wa beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe ṣe ki oun sọ ọ fun awọn eniyan ki wọn le yọ ki wọn si dunnú si dáadáa? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa paya pe ki wọn ma baa gbara le e, ti iṣẹ wọn fi maa kere. Mu’aadh ko sọ hadiisi naa fun ẹnikẹni afi ṣiwaju iku rẹ; ni ti ipaya kikosi inu ẹṣẹ fifi imọ pamọ.
Hadeeth details

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba sọ ti o si jẹrii pẹlu ahọn rẹ pe “LAA ILAAHA ILLALLOHU”, o n túmọ̀ si pe: Ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ afi Ọlọhun, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn jọsin fun yatọ si Ọlọhun, ti o bọpa-bọsẹ kuro nibi gbogbo awọn ẹsin yatọ si Isilaamu, dajudaju dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ jẹ eewọ fun awọn Musulumi, ohun ti ó kàn wa ni eyi ti o han ninu iṣẹ rẹ, wọn ko nii gba dukia rẹ, wọn ko si nii ta ẹjẹ rẹ silẹ, afi ti o ba da ẹṣẹ kan tabi wuwa ọdanran kan ti o maa sọ ìyẹn di dandan ni ìbámu si awọn idajọ Isilaamu. Ati pe Ọlọhun ni yoo ṣe ìṣirò rẹ ni ọjọ igbedide, ti o ba jẹ olododo yoo san an lẹsan, ti o ba jẹ sọbẹ-selu yoo fi iya jẹ ẹ.
Hadeeth details

Arakunrin kan beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa pe iroyin meji naa wo ni yoo sọ wiwọ alujanna di dandan, ati ti yoo sọ wiwọ ina di dandan? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe: Dajudaju ìròyìn ti yoo sọ wiwọ alujanna di dandan ni ki ọmọniyan ku ti o si n jọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọn, Ati pe iroyin ti yoo sọ wiwọ ina di dandan ni ki ọmọniyan ku ti o si n da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun ti yoo wa orogun ati olubakẹgbẹ fun Ọlọhun nibi ìní ẹtọ si ìjọsìn Rẹ tabi nibi jijẹ Oluwa Rẹ tabi nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ.
Hadeeth details

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fun wa pe dajudaju ẹni ti o ba yi nnkan kan ninu nnkan ti o jẹ dandan lati jẹ ti Ọlọhun fun ẹni ti o yàtọ̀ si I, gẹgẹ bii pipe ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- tabi wiwa iranlọwọ lọ sọdọ ẹni ti o yàtọ̀ si I, ti o si ku lori rẹ, dajudaju o maa wa ninu awọn ara ina. Ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- ṣalekun pe dajudaju ẹni ti o ba ku ti ko da nnkan kan pọ mọ Ọlọhun, dajudaju ibuṣẹripadasi rẹ ni alujanna.
Hadeeth details

Nigba ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - rán muaz ọmọ Jabal - ki Ọlọhun yọnu si i - lọ sí ilu Yemen lati lọ kéde ẹ̀sìn Ọlọhun fún wọn, kí ó sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ẹ̀sìn Islam, ó ṣalaye fun un pé dajudaju ó máa ṣalabapade awọn ọmọ Kristẹni kan nibẹ; nitori naa, ki o gbaradi fun wọn, lẹyin naa, ki o bẹrẹ ikede ẹsin Islam fun wọn pẹlu sísọ nkan tó pataki julọ, lẹyin naa ki o wá sọ nkan tó pataki tèlé e, Kí ó kọ́kọ́ pè wọ́n lọ síbi ṣiṣatunṣe igbagbọ wọn; iyẹn ni pé kí wọ́n jẹrii pé dajudaju kò sí ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, ati pé dajudaju Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní n ṣe; Nítorí pé eyi ni ó máa mú wọn wọ inu ẹsin Islam, tí wọ́n bá ti gbà lati ṣe iyẹn, kí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ waa pa wọ́n laṣẹ pé kí wọ́n maa gbé ìrun duro; nitori pe irun ni iṣẹ ọranyan tí ó tóbi jùlọ lẹyin tí a bá ti ṣe Ọlọhun lọ́kan, tí wọ́n bá gbé irun naa duro, kí o pa àwọn olówó inu wọn láṣẹ pé kí wọ́n yọ zakat owó wọn fún àwọn tálákà inu wọn, lẹ́yìn náà, Anabi ṣe ìkìlọ̀ fún Muaz pé kó má ṣe gba owó tó níye lórí jù lọ; nitori pe eyi tó jẹ́ ọranyan ni eyi tó wà ní iwọntun-wọnsì lẹyin naa, ó tún gbà á nímọ̀ràn pé kó jìnà sí àbòsí; nitori ki ẹni tí ó bá ṣabosi sí má baa ṣepe fun un, nitori pé dajudaju adura rẹ̀ maa gbà.
Hadeeth details

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fun wa ni iro pé dajudaju ẹniti ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ oun ni ọjọ Igbende ni ẹnikẹni tí ó bá sọ pé: "Ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah pẹlu ododo lati inu ọkan rẹ̀" iyẹn ni pe: ko si ẹnikẹni ti a gbọdọ jọsin fun pẹlu ododo ayafi Ọlọhun Allah, ati pe ó gbọdọ là kuro nibi ẹbọ ati kárími.
Hadeeth details

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju igbagbọ jẹ awọn ipin kan ati awọn iwa ti wọn pọ, o ko awọn iṣẹ ati awọn adisọkan ati awọn ọrọ kan sinu. Ati pe eyi to ga julọ ninu iwa igbagbọ ti o si daa julọ nibẹ ni gbolohun: “Laa ilaaha illallohu”, ni mimọ ìtumọ̀ rẹ, ni ṣíṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti o da le lori, bii pe dajudaju Ọlọhun ni Ọlọhun Ọba Ọkan ṣoṣo ti O lẹtọọ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo yatọ si ẹni ti o yatọ si I. Ati pe eyi ti o kere julọ ninu awọn iṣẹ igbagbọ ni mimu gbogbo nnkan ti o le ko suta ba awọn eniyan kuro ni awọn oju ọna wọn. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju itiju wa ninu iwa igbagbọ, oun ni awọn iwa kan ti o maa n muni ṣe nǹkan daadaa, ti o si maa n muni gbé iwa buruku ju silẹ.
Hadeeth details